Quantcast
Channel: OnIslam Africa
Viewing all articles
Browse latest Browse all 474

Irun Wakati Marun; Kini Itumo Re?

$
0
0

::jseblod::onislam_article::/jseblod::
::onislamarticleaction::::/onislamarticleaction::
::artpretitle:: ::/artpretitle::
::artsubtitle:: ::/artsubtitle::
::artseries:: ::/artseries::
::artlead::Aimoye ona ninu Alkurani ni Allah ti so fun wa wipe ki a tele ase owun ki a si tele ikose Asiwaju Eda Muhammad (Ike Olorun ki o ma baa), gbogbo eniti o ba ni igbagbo ninu Olorun gbodo tele ilana Ojise Olorun.::/artlead::
::artepigraph:: ::/artepigraph::
::artbody::

Ibeere:

Asalam Alaykum

Kini idi Pataki ti Irun oranyan fi je wakati marun? Kilode ti ko je wakati mefa? A ti wipe se asiri kan wa nibi onka yii?

Idahun: Wa `alaykum as-salamu wa rahmatullahi wa barakatuh.

Ope fun Olorun, ike ati ige ki o ma baa ojise Olorun Anabi Muhammad.

Adupe lowo onibere yii fun afokantan ti won ni siwa lati bere ibeere yi lowo wa, a be Olorun ki o maa ranwa lowo lori gbogbo awon igbese wa ki o si fi awon ise yii sinu akosile daada fun wa.

Aimoye ona ninu Alkurani ni Allah ti so fun wa wipe ki a tele ase ohun ki a si tele ikose Asiwaju Eda Muhammad (Ike Olorun ki o ma baa), gbogbo eniti o ba ni igbagbo ninu Olorun gbodo tele ilana Ojise Olorun, Olorun so ninu alkurani wipe:  { Gbe irun duro ni (igba) iseri wale orun titi di (igba) okunkun oru atipe kewu kike (inu irun) ti owuro kutu, dajudaju kewu kike (inu irun) ti owuro kutu je ohun ti a jeri (re)}. (Suratu Israi  17: 78)

Fun idi eyi, lati iyale ita titi ti okunkun o fi kun ati titi di owuro kutu ni a o ma ba Olorun Oba soro pelu Irun kiki.

Read Also:

Irin-ajo nla Israa’ ati Mi`raj ti Asiwaju Eda se nigba aiye re lo si Sanmo keje lo si odo Olorun Oba Aseda iye ati orun, apadabo irin-ajo yii ni a ti ri irun wakati marun ati onka irun kookan, Anobi kii awon irun yii o si fi ko awon Musulumi wipe bi ohun  ti kii yii ni ki won o ma kii.

Ife ti Olorun Oba Aleke Ola ni si awa eru Re ni O fi se awon irun won yii be, gbogbo igba ni Allah fe ki a ma ba Owun soro.

Ki a gbe lati irun idaji, irun alafajari Fajr ni o bere ojo wa, saaju ki a to se ohunkohun ni irun yii ma n je kiki, leyin irun yii ni a o bere ise ojo wa ti olukuluku o jade lati wa ije ati imu re lo.

Olorun ko fe ki a jina si ohun leyin ti a fi irun Fajr bere ojo wa, o fi irun Ayila Zuhr si asiko ti a wa loju ise iyen ni osan gangan, ki eniyan ma sise lowo ki o dide lo ba Olorun Oba re soro oore nla ni, iberu Allah yio tun lekun fun eni na.

Leyin ti Ojo ba n lo si opin ni owo irole, Irun alasari Asr o wole lati kii. Ni kete ti oorun ba wo a o dide ki irun Magiribi, ti oru ba tun ruu ti ile suu irun Ishaa o je kiki.

A o ri wipe Olorun pin awon irun yii ni deede awon asiko ti a n lo ni ojumo, kofi asiko Kankan sile lai je wipe a ba ohun soro pelu ope, eyin ati ibeere ohun ti a fe.

Ife ti Olorun Aleke Ola ni si awa eru Re ni o fi se awon irun won yii be, gbogbo igba ni Allah fe ki a ma ba Owun soro.
Ninu itele ikose Ojise Olorun (Ike Olorun ki o ma baa)  ni ki a ma ki irun ni jamoh iyen ni masalasi, lati ibi pi pade ni masalasi loore koore a o ma ri ara wa ba soro lori oro igbese aiye, awujo ati awon nkan miran ti o le je anfani fun gbogbo Musulumi, gege bi ase mo wipe irun jamoh ni oore ju irun adaki lo.

Lati bi irun yii ni a o ti mo iye awa Musulumi ti a wa ni ayika ati ni adugbo. E jeki a wo iye irun ti a n ki ni ojumo e wo iye igba ti a o ma pade ni masalasi, ki a tun wo iye igba ti a mo ba ara wa soro nipa oro esin ati oro igbese aiye wa, ife Olorun si awa erusin Re ni O fi gbe irun wakati marun kale fun wa ki o le se deede asiko ti a n lo.

A  be Olorun ki O gba irun ti a n ki ni esin fun wa ki otun se ijosin re ni irorun fun wa.

::/artbody::
::artendnote:: ::/artendnote::
::artfootnote:: ::/artfootnote::
::artmainimage::oimedia/onislamen/images/mainimages/Irun-Wakati-Marun-Kini-Itumo-Re.jpg::/artmainimage::
::artcaption:: ::/artcaption::
::artalt:: ::/artalt::
::artauthor::12811::/artauthor::
::artboximage::::/artboximage::
::artinterviewer:: ::/artinterviewer::
::artcompiler:: ::/artcompiler::
::artreviewer:: ::/artreviewer::
::arttranslator:: ::/arttranslator::
::artsource:: ::/artsource::
::artreference:: ::/artreference::
::artlink1:: ::/artlink1::
::artlinkurl1:: ::/artlinkurl1::
::artlink2:: ::/artlink2::
::artlinkurl2:: ::/artlinkurl2::
::artlink3:: ::/artlink3::
::artlinkurl3:: ::/artlinkurl3::
::artlink4:: ::/artlink4::
::artlinkurl4:: ::/artlinkurl4::
::artlink5:: ::/artlink5::
::artlinkurl5:: ::/artlinkurl5::
::button_submit::::/button_submit::
::jseblodend::::/jseblodend::

Viewing all articles
Browse latest Browse all 474

Trending Articles