::jseblod::onislam_article::/jseblod::
::onislamarticleaction::::/onislamarticleaction::
::artpretitle:: ::/artpretitle::
::artsubtitle:: ::/artsubtitle::
::artseries:: ::/artseries::
::artlead::Oranyan ni fun Musulumi lati maa se daada si awon obi mejeeji paapa julo Iya, koda ki o je wipe awon obi yii kiise Musulumi, Islamu pawa lase wipe ki a ma dun won ninu ni gbogbo igba.::/artlead::
::artepigraph:: ::/artepigraph::
::artbody::
Ibeere: Eyin onimimo, Asalam Alaykum. Kini owun ti Islamu so nipa ajodun ojo Iya? Nje ajodundun tako ilana Islamu bi?
Idahun : Wa `alaykum As-Salamu wa Rahmatullahi wa Barakatuh.
Gbogbo Ope ti Olohun ni, ike ati ige ko lo ba Anobi wa Muhammad.
A dupe lowo onibeere fun ifokantan yin lati beere oro yii lodo wa, a be Olohun Alaanu ki ofi gbogbo wa mo ona ododo ati otito.
Siwaju, oranyan ni fun Musulumi lati maa se daada si awon obi mejeeji paapa julo Iya, koda ki o je wipe awon obi yii kiise Musulumi, Islamu pawa lase wipe ki a ma dun won ninu ni gbogbo igba.
Owun ti Islamu tako ni ki a maa kose awon elesin miran nibi awon ajodun ati awon isele ni orisirisi gege bi ajodun ojo Iya ti a nso yii, eleyi ti o n tumo si wipe a ko gbodo fun Iya ni iyi ati owo ni awon ojo miran ayafi ojo yii nikan.
Orisirisi awon oro ati isiti ni awon onimimo so lori oro yii, ninu re niyii:
Akoko; Sheikh Faysal Mawlawi, igbakeji alaga igbimo ti o mo ojuto oro ofin Islamu ati iwadi, agbegbe Europ, so wipe:
Read Also: |
Ajodun Ojo iya ti di owun ti o gbajumo ni ode oni paapa julo ni odo awon alawo funfun. Won maa se esa ojo yii loto, awon omo Okunrin ati obirin maa nse itoju iya won pupo ni ojo yii, orisirisi ebun ati owun meremere ni won o se fun Iya ni ojo na.
Gbogbo irufe ajodun bayii kosi ni odo awa Musulumi, Islamu ti se alaye awon ojo odun fun wa ni eleyii ti ko ruju rara, beeni o si lodo si awon ajodun miran bi iru ajodun Ojo Iya.
Ni otito, kosi owun ti o buru nibi ki a dun iya eni ninu pelu awon inkan aridunnu lorisirisi, sugbon ki a wa sa esa ojo kan soso ni aarin odun wipe ojo yii ni a maa fi se daada si Iya ti o bini, akoko ni wipe ko ba ojumu ki a mu ojo yii ni odun, ekeji, ki a mu ojo yii ni ojo iduunu fun Iya Islamu lodi si pupo.
Islamu pataki awon Obi pupo paapajulo iya, gbogbo ojo ni o ye ki a maa fi dun won ninu, a ko gbodo ya ojo kan si oto fun won wipe owun ni ojo idunnu won.
Siwaju si, Sheikh Yusuf al-Qaradawi, so nipa oro yii wipe: Awon Larubawa a maa kose awon alawo funfun pupo paapajulo nibi iru awon ojo ajodun bayii, won kosi gbiyanju lati mo idi pataki ti awon fi nkose won lori ojo yii.
Awon alawo funfun se akiyesi wipe awon omo ti awon nbi koma tele ase obi beeni won o maa se ojuse won gege bi omo si obi, idi niyii ti won fi se esa ojo yii fun awon omo won lati maa fi dun obi ninu paapajulo Iya.
Lati ojo to pe ni Islamu ti gbe ola, iyi ati aponle fun Iya, gbogbo ojo, igba ati asiko ni a gbodo maa fi se daada si won |
Olohun so ninu oro re wipe:
{ Atipe A pa lase fun enia pe ki o ma se daada si awon obi re mejeeji. Iya re ni oyun re ni pelu inira o si bi I ni pelu inira. Ati oyun re ati jija oyan re ogbon osu. Titi di igbati o fi dagba ti o si di omo ogoji odun, o sope: Oluwa mi fi mo mi ki nle ma dupe idera Re, eyiti O se ni idera le mi lori ati le awon obi mi mejeeji ati ki nle se ise rere ti yio dun mo O; ki O si se rere fun mi ninu awon aromodomo mi. Dajudaju emi ti ronupiwada si odo Re atipe dajudaju emi je olujuwo-juse sile fun O.} (Suratu Ahkoofi 46: 15)
Ni ipari, lati ibere pepe ni Islamu ti gbe ola, iyi ati aponle fun awon Obi paapajulo Iya, gbogbo ojo, igba ati asiko ni a gbodo maa fi se daada si won.
Ko leto ki a se esa ojo kan fun Iya ni aarin odun pelu gbogbo wahala, idamu ati inira ti o ri lati inu oyun titi di asiko yii.
Fun idi eyii, gbogbo ojo ni ojo idunnu fun Iya, gbogbo igba ni a gbodo maa fi se daada si won lati tele ase ti Olohun pa fun wa lori oro won.
{ Atipe Oluwa re palase pe: E ko gbodo sin kinikan ayafi On nikan ati ki e ma se rere fun awon obi mejeeji.} (Suratu Israai 17: 23). Odo ni oro Olohun
Olohun ni onimo julu
::/artbody::
::artendnote:: ::/artendnote::
::artfootnote:: ::/artfootnote::
::artmainimage::oimedia/onislamen/images/mainimages/mothersday_ideas_Fotor_11-05-14.jpg::/artmainimage::
::artcaption:: ::/artcaption::
::artalt:: ::/artalt::
::artauthor::12811::/artauthor::
::artboximage::::/artboximage::
::artinterviewer:: ::/artinterviewer::
::artcompiler:: ::/artcompiler::
::artreviewer:: ::/artreviewer::
::arttranslator:: ::/arttranslator::
::artsource:: ::/artsource::
::artreference:: ::/artreference::
::artlink1:: ::/artlink1::
::artlinkurl1:: ::/artlinkurl1::
::artlink2:: ::/artlink2::
::artlinkurl2:: ::/artlinkurl2::
::artlink3:: ::/artlink3::
::artlinkurl3:: ::/artlinkurl3::
::artlink4:: ::/artlink4::
::artlinkurl4:: ::/artlinkurl4::
::artlink5:: ::/artlink5::
::artlinkurl5:: ::/artlinkurl5::
::button_submit::::/button_submit::
::jseblodend::::/jseblodend::